4 OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú gbogbo awọn olori awọn enia na, ki o si so wọn rọ̀ si õrùn niwaju OLUWA, ki imuna ibinu OLUWA ki o le yipada kuro lọdọ Israeli.
5 Mose si wi fun awọn onidajọ Israeli pe, Ki olukuluku nyin ki o pa awọn enia rẹ̀ ti o dàpọ mọ́ Baali-peoru.
6 Si kiyesi i, ọkan ninu awọn ọmọ Israeli wá o si mú obinrin Midiani kan tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ wá li oju Mose, ati li oju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ti nsọkun ni ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
7 Nigbati Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ri i, o dide lãrin ijọ, o si mú ọ̀kọ kan li ọwọ́ rẹ̀;
8 O si tọ̀ ọkunrin Israeli na lọ ninu agọ́, o si fi gún awọn mejeji li agunyọ, ọkunrin Israeli na, ati obinrin na ni inu rẹ̀. Àrun si da lãrin awọn ọmọ Israeli.
9 Awọn ti o si kú ninu àrun na jẹ́ ẹgba mejila.
10 OLUWA si sọ fun Mose pe,