5 Mose si wi fun awọn onidajọ Israeli pe, Ki olukuluku nyin ki o pa awọn enia rẹ̀ ti o dàpọ mọ́ Baali-peoru.
6 Si kiyesi i, ọkan ninu awọn ọmọ Israeli wá o si mú obinrin Midiani kan tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ wá li oju Mose, ati li oju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ti nsọkun ni ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
7 Nigbati Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ri i, o dide lãrin ijọ, o si mú ọ̀kọ kan li ọwọ́ rẹ̀;
8 O si tọ̀ ọkunrin Israeli na lọ ninu agọ́, o si fi gún awọn mejeji li agunyọ, ọkunrin Israeli na, ati obinrin na ni inu rẹ̀. Àrun si da lãrin awọn ọmọ Israeli.
9 Awọn ti o si kú ninu àrun na jẹ́ ẹgba mejila.
10 OLUWA si sọ fun Mose pe,
11 Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ti yi ibinu mi pada kuro lara awọn ọmọ Israeli, nipa itara rẹ̀ nitori mi lãrin wọn, ki emi ki o máṣe run awọn ọmọ Israeli ninu owú mi.