2 Kà iye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, gbogbo awọn ti o le lọ si ogun ni Israeli.
3 Mose ati Eleasari alufa si sọ fun wọn ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, lẹba Jordani leti Jeriko pe,
4 Ẹ kà iye awọn enia na, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati fun awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá.
5 Reubeni, akọ́bi Israeli: awọn ọmọ Reubeni; Hanoki, lati ọdọ ẹniti idile awọn ọmọ Hanoki ti wá: ti Pallu, idile awọn ọmọ Pallu:
6 Ti Hesroni, idile awọn ọmọ Hesroni: ti Karmi, idile awọn ọmọ Karmi.
7 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Reubeni: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanlelogun o le ẹgbẹsan o din ãdọrin.
8 Ati awọn ọmọ Pallu; Eliabu.