30 Wọnyi li awọn ọmọ Gileadi: ti Ieseri, idile Ieseri: ti Heleki, idile Heleki:
31 Ati ti Asrieli, idile Asrieli: ati ti Ṣekemu, idile Ṣekemu:
32 Ati Ṣemida, idile awọn ọmọ Ṣemida: ati ti Heferi, idile awọn ọmọ Heferi.
33 Selofehadi ọmọ Heferi kò si lí ọmọkunrin, bikọse ọmọbinrin: orukọ awọn ọmọbinrin Selofehadi a ma jẹ Mala, ati Noa, ati Hogla, Milka, ati Tirsa.
34 Wọnyi ni idile Manasse, ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin.
35 Wọnyi li awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣutela, idile awọn ọmọ Ṣutela: ti Bekeri, idile awọn ọmọ Bekeri: ti Tahani, idile awọn ọmọ Tahani.
36 Wọnyi li awọn ọmọ Ṣutela: ti Erani, idile awọn ọmọ Erani.