34 Wọnyi ni idile Manasse, ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin.
35 Wọnyi li awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣutela, idile awọn ọmọ Ṣutela: ti Bekeri, idile awọn ọmọ Bekeri: ti Tahani, idile awọn ọmọ Tahani.
36 Wọnyi li awọn ọmọ Ṣutela: ti Erani, idile awọn ọmọ Erani.
37 Wọnyi ni idile awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le ẹdẹgbẹta. Wọnyi li awọn ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn.
38 Awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ti Bela, idile awọn ọmọ Bela: ti Aṣbeli, idile awọn ọmọ Aṣbeli: ti Ahiramu, idile awọn ọmọ Ahiramu.
39 Ti Ṣefamu, idile awọn ọmọ Ṣufamu: ti Hufamu, idile awọn ọmọ Hufamu.
40 Awọn ọmọ Bela si ni Ardi ati Naamani: ti Ardi, idile awọn ọmọ Ardi: ati ti Naamani, idile awọn ọmọ Naamani.