50 Wọnyi ni idile ti Naftali gẹgẹ bi idile wọn: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le egbeje.
51 Wọnyi li a kà ninu awọn ọmọ Israeli, ọgbọ̀n ọkẹ, o le ẹgbẹsan o din ãdọrin.
52 OLUWA si sọ fun Mose pe,
53 Fun awọn wọnyi ni ki a pín ilẹ na ni iní gẹgẹ bi iye orukọ.
54 Fun awọn ti o pọ̀ ni ki iwọ ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun awọn ti o kére ni ki iwọ ki o fi diẹ fun: ki a fi ilẹ-iní olukuluku fun u gẹgẹ bi iye awọn ti a kà ninu rẹ̀.
55 Ṣugbọn kèké li a o fi pín ilẹ na: gẹgẹ bi orukọ ẹ̀ya awọn baba wọn ni ki nwọn ki o ní i.
56 Gẹgẹ bi kèké ni ki a pín ilẹ-iní na lãrin awọn pupọ̀ ati diẹ.