5 Mose si mú ọ̀ran wọn wá siwaju OLUWA.
6 OLUWA si sọ fun Mose pe,
7 Awọn ọmọbinrin Selofehadi sọ rere: nitõtọ, fun wọn ni ilẹ-iní kan lãrin awọn arakunrin baba wọn; ki iwọ ki o si ṣe ki ilẹ-iní baba wọn ki o kọja sọdọ wọn.
8 Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ọkunrin kan ba kú, ti kò si lí ọmọkunrin, njẹ ki ẹnyin ki o ṣe ki ilẹ-iní rẹ̀ ki o kọja sọdọ ọmọbinrin rẹ̀.
9 Bi on kò ba si lí ọmọbinrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-ini rẹ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀.
10 Bi on kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun awọn arakunrin baba rẹ̀:
11 Bi baba rẹ̀ kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun ibatan rẹ̀, ti o sunmọ ọ ni idile rẹ̀, on ni ki o jogún rẹ̀: yio si jasi ìlana idajọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.