8 Ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ: bi ẹbọ ohunjijẹ ti owurọ̀, ati bi ẹbọ ohunmimu rẹ̀ ni ki iwọ ki o ṣe, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.
9 Ati li ọjọ́-isimi akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan alailabùku, ati idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi oróro pò, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀:
10 Eyi li ẹbọ sisun ọjọjọ́ isimi, pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
11 Ati ni ìbẹrẹ òṣu nyin ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun kan si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu meji, ati àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku;
12 Ati idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun akọmalu kan, fun ẹbọ ohunjijẹ; ati idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun àgbo kan, fun ẹbọ ohunjijẹ:
13 Ati idamẹwa òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun ọdọ-agutan kan fun ẹbọ ohunjijẹ; fun ẹbọ sisun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
14 Ki ẹbọ ohunmimu wọn ki o jẹ́ àbọ òṣuwọn hini ti ọti-waini fun akọmalu kan, ati idamẹta òṣuwọn hini fun àgbo kan, ati idamẹrin òṣuwọn hini fun ọdọ-agutan kan: eyi li ẹbọ sisun oṣuṣù ni gbogbo oṣù ọdún.