27 Ati ti Kohati ni idile awọn ọmọ Amramu, ati idile ti awọn ọmọ Ishari, ati idile ti awọn ọmọ Hebroni, ati idile ti awọn ọmọ Usieli: wọnyi ni idile awọn ọmọ Kohati.
28 Gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ẹgba mẹrin o le ẹgbẹta, ti nṣe itọju ibi-mimọ́.
29 Awọn idile ti awọn ọmọ Kohati ni ki o pagọ́ lẹba agọ́ si ìha gusù.
30 Ati Elisafani ọmọ Usieli ni ki o ṣe olori ile baba awọn idile awọn ọmọ Kohati.
31 Apoti, ati tabeli, ati ọpá-fitila, ati pẹpẹ wọnni, ati ohun-èlo ibi-mimọ́, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ alufa, ati aṣọ-tita, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin rẹ̀, ni yio jẹ́ ohun itọju wọn.
32 Eleasari ọmọ Aaroni alufa ni yio si ṣe olori awọn olori awọn ọmọ Lefi, on ni yio si ma ṣe itọju awọn ti nṣe itọju ibi-mimọ́.
33 Ti Merari ni idile awọn ọmọ Mali, ati idile awọn ọmọ Musi: wọnyi ni idile Merari.