1 MOSE si sọ fun awọn olori awọn ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli, wipe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ.
2 Bi ọkunrin kan ba jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, tabi ti o ba bura lati fi dè ara rẹ̀ ni ìde, ki on ki o máṣe bà ọ̀rọ rẹ̀ jẹ; ki on ki o ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ẹnu rẹ̀ jade.
3 Bi obinrin kan pẹlu ba si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, ti o si dè ara rẹ̀ ni ìde, ni ile baba rẹ̀ ni ìgba ewe rẹ̀;
4 Ti baba rẹ̀ si gbọ́ ẹjẹ́ rẹ̀, ati ìde rẹ̀ ti o fi dè ara rẹ̀, ti baba rẹ̀ ba si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i; njẹ ki gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ ki o duro, ati gbogbo ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro.
5 Ṣugbọn bi baba rẹ̀ ba kọ̀ fun u li ọjọ́ na ti o gbọ́; kò sí ọkan ninu ẹjẹ́ rẹ̀, tabi ninu ìde ti o fi dè ara rẹ̀, ti yio duro: OLUWA yio si darijì i, nitoriti baba rẹ̀ kọ̀ fun u.
6 Bi o ba si kúku li ọkọ, nigbati o jẹ́ ẹjẹ́, tabi ti o sọ̀rọ kan lati ẹnu rẹ̀ jade, ninu eyiti o fi dè ara rẹ̀ ni ìde;