1 NJẸ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ní ọ̀pọlọpọ ohunọ̀sin: nwọn si ri ilẹ Jaseri, ati ilẹ Gileadi, si kiyesi i, ibẹ̀ na, ibi ohunọ̀sin ni;
2 Awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni si wá, nwọn si sọ fun Mose, ati fun Eleasari alufa ati fun awọn olori ijọ pe,
3 Atarotu, ati Diboni, ati Jaseri, ati Nimra, ati Heṣboni, ati Eleale, ati Ṣebamu, ati Nebo, ati Beoni.
4 Ilẹ na ti OLUWA ti kọlù niwaju ijọ Israeli, ilẹ ohunọ̀sin ni, awa iranṣẹ rẹ si ní ohunọ̀sin.
5 Nwọn si wipe, Bi awa ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, jẹ ki a fi ilẹ yi fun awọn iranṣẹ rẹ fun ilẹ-iní; ki o má si ṣe mú wa gòke Jordani lọ.