4 Bi awọn ara Egipti ti nsinkú gbogbo awọn akọ́bi wọn ti OLUWA kọlù ninu wọn: lara awọn oriṣa wọn pẹlu li OLUWA ṣe idajọ.
5 Awọn ọmọ Israeli si ṣí kuro ni Ramesesi, nwọn si dó si Sukkotu.
6 Nwọn si ṣí kuro ni Sukkotu, nwọn si dó si Etamu, ti mbẹ leti aginjù.
7 Nwọn si ṣí kuro ni Etamu, nwọn si pada lọ si Pi-hahirotu, ti mbẹ niwaju Baali-sefoni: nwọn si dó siwaju Migdolu.
8 Nwọn si ṣí kuro niwaju Hahirotu, nwọn si là ãrin okun já lọ si aginjù: nwọn si rìn ìrin ijọ́ mẹta li aginjù Etamu, nwọn si dó si Mara.
9 Nwọn si ṣí kuro ni Mara, nwọn si wá si Elimu: ni Elimu ni orisun omi mejila, ati ãdọrin igi ọpẹ wà; nwọn si dó sibẹ̀.
10 Nwọn si ṣí kuro ni Elimu, nwọn si dó si ẹba Okun Pupa.