2 Nwọn si wipe, OLUWA ti paṣẹ fun oluwa mi lati fi keké pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli ni iní: a si fi aṣẹ fun oluwa mi lati ọdọ OLUWA wá lati fi ilẹiní Selofehadi arakunrin wa fun awọn ọmọ rẹ̀ obinrin.
3 Bi a ba si gbé wọn niyawo fun ẹnikan ninu awọn ọmọkunrin ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli miran, nigbana ni a o gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní awọn baba wa, a o si fi kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà a kuro ninu ipín ilẹ-iní ti wa.
4 Ati nigbati ọdún jubeli awọn ọmọ Israeli ba dé, nigbana li a o fi ilẹ-iní wọn kún ilẹ-iní ẹ̀ya ti a gbé wọn si: bẹ̃li a o si gbà ilẹ-iní wọn kuro ninu ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba wa.
5 Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, pe, Ẹ̀ya awọn ọmọ Josefu fọ̀ rere.
6 Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ nipa ti awọn ọmọbinrin Selofehadi, wipe, Ki nwọn ki o ṣe aya ẹniti o wù wọn; kiki pe, ninu idile ẹ̀ya baba wọn ni ki nwọn ki o gbeyawo si.
7 Bẹ̃ni ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli ki yio yi lati ẹ̀ya de ẹ̀ya: nitori ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o le faramọ́ ilẹ-iní ẹ̀ya awọn baba rẹ̀:
8 Ati gbogbo awọn ọmọbinrin, ti o ní ilẹ-iní ninu ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli, ki o ṣe aya fun ọkan ninu idile ẹ̀ya baba rẹ̀, ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o le ma jogún ilẹ-iní awọn baba rẹ̀.