9 Bẹ̃ni ki ilẹ-iní ki o máṣe yi lati ẹ̀ya kan lọ si ẹ̀ya keji; ṣugbọn ki olukuluku ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli ki o faramọ́ ilẹ-iní tirẹ̀.
10 Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọbinrin Selofehadi ṣe:
11 Nitoripe a gbé Mala, Tirsa, ati Hogla, ati Milka, ati Noa, awọn ọmọbinrin Selofehadi niyawo fun awọn ọmọ arakunrin baba wọn.
12 A si gbé wọn niyawo sinu idile awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu, ilẹ-ini wọn si duro ninu ẹ̀ya idile baba wọn.
13 Wọnyi ni aṣẹ ati idajọ ti OLUWA palaṣẹ fun awọn ọmọ Israeli lati ọwọ́ Mose, ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.