33 Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn gbogbo, ninu agọ́ ajọ, labẹ Itamari ọmọ Aaroni alufa.
34 Mose ati Aaroni ati awọn olori ijọ awọn enia si kà awọn ọmọ Kohati nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn,
35 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ:
36 Awọn ti a si kà ninu wọn nipa idile wọn jẹ́ ẹgbẹrinla o din ãdọta.
37 Wọnyi li awọn ti a kà ni idile awọn ọmọ Kohati, gbogbo awọn ti o le ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ, ti Mose ati Aaroni kà, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.
38 Awọn ti a si kà ninu awọn ọmọ Gerṣoni, nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn,
39 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na, fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ,