43 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na, fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ,
44 Ani awọn ti a kà ninu wọn nipa idile wọn jẹ́ ẹgbẹrindilogun.
45 Wọnyi li awọn ti a kà ninu idile awọn ọmọ Merari, ti Mose ati Aaroni kà gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.
46 Gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, ti Mose ati Aaroni ati awọn olori Israeli kà, nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn,
47 Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wá lati ṣe iṣẹ-ìsin, ati iṣẹ ẹrù ninu agọ́ ajọ,
48 Ani awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgbẹtalelẹgbarin o din ogun.
49 Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA li a kà wọn nipa ọwọ́ Mose, olukuluku nipa iṣẹ-ìsin rẹ̀, ati gẹgẹ bi ẹrù rẹ̀: bẹ̃li a ti ọwọ́ rẹ̀ kà wọn, bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.