5 Nigbati ibudó ba si ṣí siwaju, Aaroni o wá, ati awọn ọmọ rẹ̀, nwọn o si bọ́ aṣọ-ikele rẹ̀ silẹ, nwọn o si fi i bò apoti ẹrí;
6 Nwọn o fi awọ seali bò o, nwọn o si nà aṣọ kìki alaró bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá nì bọ̀ ọ.
7 Ati lori tabili àkara ifihàn nì, ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, ki nwọn ki o si fi awopọkọ sori rẹ̀, ati ṣibi ati awokòto, ati ìgo ohun didà: ati àkara ìgbagbogbo nì ki o wà lori rẹ̀:
8 Ki nwọn ki o si nà aṣọ ododó bò wọn, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò o, ki nwọn ki o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ.
9 Ki nwọn ki o si mú aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi bò ọpá-fitila nì, ati fitila rẹ̀, ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo oróro rẹ̀, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ rẹ̀.
10 Ki nwọn ki o si fi on ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀ sinu awọ seali, ki nwọn ki o si gbé e lé ori igi.
11 Ati lori pẹpẹ wurà ni ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, nwọn o si fi awọ seali bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ.