10 Ati ohun mimọ́ olukuluku, ki o jẹ́ tirẹ̀: ohunkohun ti ẹnikan ba fi fun alufa ki o jẹ́ tirẹ̀.
11 OLUWA si sọ fun Mose pe,
12 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Bi aya ọkunrin kan ba yapa, ti o si ṣẹ̀ ẹ,
13 Ti ọkunrin kan si bá a dàpọ, ti o si pamọ́ fun ọkọ rẹ̀, ti o si sin, ti on si di ẹni ibàjẹ́, ti kò si sí ẹlẹri kan si i, ti a kò si mú u mọ ọ,
14 Ti ẹmi owú ba dé si i, ti o si njowú aya rẹ̀, ti obinrin na si di ẹni ibàjẹ́: tabi bi ẹmi owú ba dé si i, ti o si njowú aya rẹ̀, ṣugbọn ti on kò di ẹni ibàjẹ́:
15 Nigbana ni ki ọkunrin na ki o mú aya rẹ́ tọ̀ alufa wá, ki o si mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá fun u, idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun barle; ki o máṣe dà oróro sori rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe fi turari sinu rẹ̀; nitoripe ẹbọ ohunjijẹ owú ni, ẹbọ ohunjijẹ iranti ni, ti nmú irekọja wá si iranti.
16 Ki alufa na ki o si mú u sunmọtosi, ki o mu u duro niwaju OLUWA: