2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ọkunrin kan tabi obinrin kan ba yà ara wọn sapakan lati ṣe ileri ti Nasiri, lati yà ara wọn si OLUWA:
3 Ki o yà ara rẹ̀ kuro ninu ọti-waini tabi ọti lile; ki o má si ṣe mu ọti-waini kikan, tabi ọti lile ti o kan, ki o má si ṣe mu ọti eso-àjara kan, bẹ̃ni kò gbọdọ jẹ eso-àjara tutù tabi gbigbẹ.
4 Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ ni ki o gbọdọ jẹ ohun kan ti a fi eso-àjara ṣe, lati kóro rẹ̀ titi dé ẽpo rẹ̀.
5 Ni gbogbo ọjọ́ ileri ìyasapakan rẹ̀, ki abẹ kan máṣe kàn a li ori: titi ọjọ́ wọnni yio fi pé, ninu eyiti o yà ara rẹ̀ si OLUWA, ki o jẹ́ mimọ́, ki o si jẹ ki ìdi irun ori rẹ̀ ki o ma dàgba.
6 Ni gbogbo ọjọ́ ti o yà ara rẹ̀ si OLUWA, on kò gbọdọ sunmọ okú.
7 On kò gbọdọ sọ ara rẹ̀ di alaimọ́ nitori baba rẹ̀, tabi nitori iya rẹ̀, nitori arakunrin rẹ̀, tabi nitori arabinrin rẹ̀, nigbati nwọn ba kú: nitoripe ìyasapakan Ọlọrun rẹ̀ mbẹ li ori rẹ̀.
8 Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀, mimọ́ li on fun OLUWA.