6 Ni gbogbo ọjọ́ ti o yà ara rẹ̀ si OLUWA, on kò gbọdọ sunmọ okú.
7 On kò gbọdọ sọ ara rẹ̀ di alaimọ́ nitori baba rẹ̀, tabi nitori iya rẹ̀, nitori arakunrin rẹ̀, tabi nitori arabinrin rẹ̀, nigbati nwọn ba kú: nitoripe ìyasapakan Ọlọrun rẹ̀ mbẹ li ori rẹ̀.
8 Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀, mimọ́ li on fun OLUWA.
9 Bi enia kan ba si kú lojiji lẹba ọdọ rẹ̀, ti o ba si bà ori ìyasapakan rẹ̀ jẹ́; nigbana ni ki o fá ori rẹ̀ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀, ni ijọ́ keje ni ki o fá a.
10 Ati ni ijọ́ kẹjọ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ:
11 Ki alufa ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun, ki o si ṣètutu fun u, nitoriti o ṣẹ̀ nipa okú, ki o si yà ori rẹ̀ simimọ́ li ọjọ́ na.
12 Ki o si yà ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ simimọ́ si OLUWA, ki o si mú akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹbi: ṣugbọn ọjọ́ ti o ti ṣaju yio di asan, nitoripe ìyasapakan rẹ̀ bàjẹ́.