29 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Eliabu ọmọ Heloni.
30 Li ọjọ́ kẹrin Elisuri ọmọ Ṣedeuri, olori awọn ọmọ Reubeni;
31 Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ;
32 Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
33 Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
34 Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
35 Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Elisuri ọmọ Ṣedeuri.