20 Nigba miran awọsanma a wà li ọjọ́ diẹ lori agọ́ na; nigbana gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a dó, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nwọn a si ṣí.
21 Nigba miran awọsanma a duro lati alẹ titi di owurọ̀; nigbati awọsanma si ṣí soke li owurọ̀, nwọn a ṣí: iba ṣe li ọsán tabi li oru, ti awọsanma ba ká soke, nwọn a ṣí.
22 Bi ijọ́ meji ni, tabi oṣù kan, tabi ọdún kan, ti awọsanma ba pẹ lori agọ́ na, ti o simi lé e, awọn ọmọ Israeli a dó, nwọn ki si iṣí: ṣugbọn nigbati o ba ká soke, nwọn a ṣí.
23 Nipa aṣẹ OLUWA nwọn a dó, ati nipa aṣẹ OLUWA nwọn a ṣí: nwọn a ma ṣe afiyesi aṣẹ OLUWA, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.