4 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o ma pa ajọ irekọja mọ́:
5 Nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla, oṣù kini, li aṣalẹ ni ijù Sinai: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe.
6 Awọn ọkunrin kan wà ti nwọn ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́, nwọn kò si le ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ na: nwọn si wá siwaju Mose ati siwaju Aaroni li ọjọ́ na:
7 Awọn ọkunrin na si wi fun u pe, Awa ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́: nitori kili a o ṣe fàsẹhin ti awa ki o le mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ Israeli?
8 Mose si wi fun wọn pe, Ẹ duro na; ki emi ki o le gbọ́ aṣẹ ti OLUWA yio pa niti nyin.
9 OLUWA si sọ fun Mose pe,
10 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ẹnikẹni ninu nyin, tabi ninu iran nyin, ba ti ipa okú di alaimọ́, tabi bi o ba wà li ọ̀na àjo jijìn rére, sibẹ̀ on o pa ajọ irekọja mọ́ fun OLUWA.