12 Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn le kò fẹ oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn kò da.
13 Ṣugbọn ẹ lọ ẹ si kọ́ bi ã ti mọ̀ eyi si, Anu li emi nfẹ, kì iṣe ẹbọ: nitori emi kò wá lati pè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.
14 Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Johanu tọ̀ ọ wá wipe, Èṣe ti awa ati awọn Farisi fi ngbàwẹ nigbagbogbo, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko gbàwẹ?
15 Jesu si wi fun wọn pe, Awọn ọmọ ile iyawo ha le gbàwẹ, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn ó gbãwẹ.
16 Ko si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun lẹ ogbologbó ẹ̀wu; nitori eyi ti a fi lẹ ẹ o mu kuro li oju ẹ̀lẹ, aṣọ na a si mã ya siwaju.
17 Bẹ̃ni ko si ẹniti ifi waini titun sinu ogbologbo igo-awọ; bi a ba ṣe bẹ̃, igo-awọ yio bẹ́, waini a si tú jade, igo-awọ a si ṣegbe; ṣugbọn waini titun ni nwọn ifi sinu igo-awọ titun, awọn mejeji a si ṣe dede.
18 Bi o ti nsọ nkan wọnyi fun wọn, kiyesi i, ijoye kan tọ̀ ọ wá, o si tẹriba fun u, wipe, Ọmọbinrin mi kú nisisiyi, ṣugbọn wá fi ọwọ́ rẹ le e, on ó si yè.