2 Èmi yóò sì tún ọ̀rọ̀ tí ó wà lórí síléètì àkọ́kọ́ tí o fọ́ kọ sórí rẹ̀. Kí o sì fi wọ́n sínú àpótí náà.”
3 Mo sì kan àpótí náà pẹ̀lú igi kaṣíà, mo sì gbẹ́ síléètì òkúta méjì náà jáde bí i ti ìṣáájú. Mo sì gòkè lọ pẹ̀lú síléètì méjèèjì lọ́wọ́ mí.
4 Olúwa tún ohun tí ó ti kọ tẹ́lẹ̀ kọ sórí síléétì wọ̀nyí. Àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó ti sọ fún un yín lórí òkè, láàrin iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀. Olúwa sì fi wọ́n fún mi.
5 Mo sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, mo sì ki àwọn síléètì òkúta náà sínú àpótí tí mo ti kàn, bí Olúwa ti pàṣẹ fún mi, wọ́n sì wà níbẹ̀ di ìsinsin yìí.
6 (Àwọn ará Ísírẹ́lì sì gbéra láti kàǹga àwọn ará a Jákánì dé Mósérà. Níbí ni Árónì kú sí, tí a sì sin ín, Élíásárì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ bí i àlùfáà.
7 Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rìn lọ sí Gúdígódà, títí dé Jótíbárà, ilẹ̀ tí o kún fún odò tí ó ń sàn.
8 Ní ìgbà yí ni Olúwa yan àwọn ọmọ Léfì láti máa ru àpótí májẹ̀mú Olúwa, láti máa dúró níwájú Olúwa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti láti fi orúkọ Olúwa súre bí wọ́n ti ń ṣe títí di òní yìí.