Deutarónómì 15:5-11 BMY

5 Kìkì bí ẹ bá gbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín tí ẹ sì kíyèsára láti máa rìn nínú gbogbo àṣẹ wọ̀nyí, tí èmi ń pa fún un yín lónìí.

6 Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín bí ó ti ṣèlérí, ẹ̀yin yóò sì máa yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ẹ kì yóò sì tọrọ. Ẹ ó ṣàkóso ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè, ṣùgbọ́n kò sí orílẹ̀ èdè tí yóò lè jọba lé e yín lórí.

7 Bí talákà kan bá wà láàrin àwọn arákùnrin yín ní èyíkèyí àwọn ìlú, ilẹ̀ náà tí Olúwa yín yóò fún un yín. Ẹ má ṣe se àìláànú bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe háwọ́ sí arákùnrin yín tí ó jẹ́ tálákà.

8 Ṣùgbọ́n ẹ lawọ́ kí ẹ sì fi tọkàntọkàn yá wọn ní ohun tí wọ́n nílò.

9 Ẹ sọ́ra kí èrò búburú kan má ṣe sí nínú àyà rẹ wí pé, “Ọdún kéje tí í ṣe ọdún ìyọ̀ǹda gbésè ti súnmọ́” nípa bẹ́ẹ̀, ojú rẹ a sì burú sí arákùnrin rẹ talákà, tí ìwọ kò sì fun ní nǹkan, o kò sì fun ní nǹkan kan. Òun a si kígbe pe olúwa nitori rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ.

10 Fún un tọkàntọkàn, láì sí ìkùnsínú, nítorí èyí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkun fún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, àti gbogbo ìdáwọ́lé rẹ.

11 A kò lè fẹ́ tálákà kù ní ilẹ̀ náà ní ìgbà gbogbo, mo pàṣẹ fún un yín láti lawọ́ sí àwọn arákùnrin yín, sí àwọn talákà àti sí àwọn aláìní, ní ilẹ̀ ẹ yín.