Deutarónómì 29:17-23 BMY

17 Ìwọ rí láàrin wọn ìríra wọn, àwọn ère àti àwọn òrìṣà igi àti ti òkúta, ti fàdákà àti ti wúrà.

18 Rí i dájú pé kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin, ìdílé tàbí ẹ̀yà láàrin yín lónìí tí ọkàn an rẹ̀ yóò yí kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa láti lọ àtí láti sin àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀ èdè náà; rí i dájú pé kò sí gbòǹgbò tí ó ń mú irú èso kíkan bẹ́ẹ̀ jáde láàrin yín.

19 Nígbà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá gbọ́ ìbúra yìí, kí ó gbàdúrà ìbùkún sórí ara rẹ̀ nígbà náà ni kí ó ronú, “Èmi yóò wà lálàáfíà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fi àáké kọ́rí nípa lílọ nínú ọ̀nà ti ara à mi.” Èyí yóò mú ìjálù wá sórí ilẹ̀ tútù àti sórí ilẹ̀ gbígbẹ bákan náà

20 Olúwa kì yóò ní ìfẹ́ sí àti dáríjìí; ìbínú àti ìtara rẹ̀ yóò jó ọkùnrin náà. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sínú ìwé yìí yóò wá sórí i rẹ̀, Olúwa yóò sì yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lábẹ́ ọ̀run.

21 Olúwa yóò sì yọ òun nìkan kúrò nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì fún àjálù, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ègún májẹ̀mú tí a kọ sí inú ìwé òfin yìí.

22 Àwọn ọmọ rẹ tí ó tẹ̀lé ìran rẹ lẹ́yìn àti àwọn àlejò tí ó wá láti ilẹ̀ jíjìn yóò rí wàhálà tí ó wá sórí ilẹ̀ àti àwọn àrùn pẹ̀lú tí Olúwa mú bá ọ.

23 Gbogbo ilẹ̀ náà yóò di imí-òórùn, àti iyọ̀, àti ìjóná tí a kò lè fi ọkàn sí, tàbí tí kò lè ṣo èso tàbí tí koríko kò lè hù nínú u rẹ̀, yóò dàbí ìbìṣubú Ṣódómù àti Gòmórà, Ádímà àti Sébóíímù, tí Olúwa bì subú nínú ìbínú u rẹ̀, àti ìkannú rẹ̀.