3 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run wa fi Ógù ọba Báṣánì àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lé wa lọ́wọ́. A pa wọ́n run láìṣẹ́ku ẹnì kankan.
4 Ní ìgbà náà ní a gba gbogbo àwọn ìlú rẹ̀. Kò sí ọ̀kankan tí a kò gbà nínú àwọn ọgọta (60) ìlú tí wọ́n ní: Gbogbo agbégbé Ágóbù, lábẹ́ ìjọba Ógù ní Báṣánì.
5 Gbogbo ìlú wọ̀nyí ní a mọ odi gíga yíká pẹ̀lú àwọn ìlẹ̀kùn àti irin. Ọ̀pọ̀ àwọn ìlú kékèké tí a kò mọ odi yíká sì tún wà pẹ̀lú.
6 Gbogbo wọn ni a parun pátapáta gẹ́gẹ́ bí á ti ṣe sí Síhónì ọba Hésíbónì, tí a pa gbogbo ìlú wọn run pátapáta: tọkùnrin tobìnrin àti àwọn ọmọ wọn.
7 Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀ṣìn àti ìkógún àwọn ìlú wọn, fún ara wa.
8 Ní ìgbà náà ni a ti gba ilẹ̀ tí ó wà ní Jọ́dánì láti odò Ánónì, títí dé orí òkè Hámónì lọ́wọ́ àwọn ọba Ámórì méjèèjì wọ̀nyí.
9 (Àwọn ará Sídónì ń pe Hámónì ní Sírónì: Àwọn Ámórì sì ń pè é ní Sénírì)