46 Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti ṣọ láàrin yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́ran àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.
47 Wọn kì í se ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jọ́dánì lọ láti gbà.”
48 Ní ọjọ́ kan náà, Olúwa sọ fún Móṣè pé,
49 “Gòkè lọ sí Ábárímù sí òkè Nébò ní Móábù, tí ó kọjú sí Jẹ́ríkò, kí o sì wo ilẹ̀ Kénánì ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Isírẹ́lì, bí ìní i wọn.
50 Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Árónì ti kú ní orí òkè Hórù tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀.
51 Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ibi omi Móríbà Kádésì ní ihà Ṣínì àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrin àwọn ọmọ Isírẹ́lì.
52 Nítorí náà, ìwọ yóò rí ilẹ̀ náà ní ọ̀kánkán, o kì yóò wọ inú rẹ̀ ilẹ̀ ti mo ti fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”