7 Mósè jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà tí ó kú, síbẹ̀ ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù.
8 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣunkún un Móṣè ní pẹ̀tẹ́lẹ́ Móábù ní ọgbọ̀n ọjọ́ títí di ìgbà tí ọjọ́ ẹkún àti ọ̀fọ̀ Móṣè parí.
9 Jóṣúà ọmọ Núnì kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n nítorí Móṣè ti gbọ́wọ́ ọ rẹ̀ lée lórí. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fetí sí i wọ́n sì ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún Mósè.
10 Láti ìgbà náà kò sì sí wòlíì tí ó dìde ní Ísírẹ́lì bí i Móṣè, ẹni tí Olúwa mọ̀ lójúkojú,
11 tí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Olúwa rán an láti lọ ṣe ní Éjíbítì sí Fáráò àti sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ àti sí gbogbo ilẹ̀ náà.
12 Nítorí kò sí ẹni tí ó tíì fi gbogbo ọ̀rọ̀ agbára hàn, tàbí ṣe gbogbo ẹ̀rù ńlá tí Móṣè fi hàn ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì.