2 Ẹ rántí bí Olúwa Ọlọ́run yín ti tọ́ ọ yín sọ́nà ní gbogbo ọ̀nà ní ihà fún ogójì ọdún wọ̀nyí láti tẹ orí i yín ba àti láti dán an yín wò kí ó báà le mọ bí ọkàn yín ti rí, bóyá ẹ ó pa òfin rẹ̀ mọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
3 Ó rẹ̀ yín sílẹ̀ nípa fífi ebi pa yín, Ó sì fi mánà bọ́ ọ yín, èyí tí ẹ kò mọ̀, tí àwọn baba yín kò mọ̀, kí ó báà lè kọ́ ọ yín pé, ènìyàn kò wà láàyè nípa oúnjẹ nìkan, bí kò ṣe ohun gbogbo tí ó jáde láti ẹnu Olúwa wá.
4 Aṣọ yín kò gbó mọ́ ọ yín lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ní ẹṣẹ̀ yín kò sì wú, ní ogójì ọdún náà.
5 Ẹ mọ̀ ní ọkàn an yín pé, bí baba ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín ń kọ́ ọ yín.
6 Torí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀.
7 Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń ṣàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.
8 Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà bálì, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pómégíránátì, òróró ólífì àti oyin.