16 O mú lára àwọn aṣọ rẹ, láti rán aṣọ aláràbarà fún ibi giga òrìṣà tí o ti ń ṣàgbèrè. Èyí kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, tàbí kó tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá.
17 O tún mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ dáradára tí mo fi wúrà àti fàdákà ṣe fún ọ láti fi yá ère ọkùnrin tí ó ń bá ọ ṣe àgbèrè papọ̀.
18 O sì wọ ẹ̀wù oníṣẹ́ ọnà rẹ fún wọn, o sì tún gbé òróró àti tùràrí mi sílẹ̀ níwájú wọn.
19 O tún gbé oúnjẹ tí mo fún ọ-ìyẹ̀fún dáradára, òróró àti oyin-fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn; ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyìí, ni Olúwa Ọlọ́run wí.
20 “ ‘Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí o bí fún mi lo ti fi rúbọ bí oúnjẹ fún àwọn òrìṣà. Ṣé ìwà àgbèrè rẹ kò ha tó bí?
21 Ẹ dú àwọn ọmọ mí lọ́rùn, o fà wọ́n fún ère gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun,
22 Nínú gbogbo iṣẹ́ ìríra àti ìwà àgbérè rẹ, o kò rántí ìgbà èwe rẹ, nígbà tó o wà ní ìhòòhò, tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀.