Ísíkẹ́lì 44:17-23 BMY

17 “ ‘Nígbà ti wọ́n wọ àwọn ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú, wọn yóò wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, wọn kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní àwọn ẹnu ọ̀nà àgbàlá ti inú tàbí ni inú ilé Ọlọ́run.

18 Wọ́n ní láti dé fìlà ọ̀gbọ̀ sí orí wọn àti àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀gbọ̀ sí ìdí wọn. Wọn kò gbọdọ̀ wọ ohunkóhun tí yóò mú wọn làágùn.

19 Nígbà tí wọ́n bá lọ sì àgbàlá òde níbi tí àwọn ènìyàn wà, wọn gbọdọ̀ bọ́ aṣọ tí wọ́n fi ń siṣẹ́ ìránṣẹ́, ki wọn sì fi wọn sílẹ̀ sí àwọn yàrá mímọ́ náà, kí wọn kí ó sì wọ aṣọ mìíràn, kí wọn kí ó má ba à sọ àwọn ènìyàn di mímọ́ nípasẹ̀ aṣọ wọn.

20 “ ‘Wọn kò gbọdọ̀ fá irun, wọn kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí irun wọn gùn, ṣùgbọ́n wọn gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí wọn wà ní gígẹ̀.

21 Àlùfáà kankan kò gbọdọ̀ mu ọtí nígbà tí ó bá wọ àgbàlá tí inú.

22 Wọn ko gbọdọ̀ fẹ́ opó ni ìyàwó, wọn kò sì gbọdọ̀ kọ ìyàwó wọn sílẹ̀; Wọ́n lè fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ti kò tí i mọ ọkùnrin rí, tí ó sì jẹ́ ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tàbí kí wọn fẹ́ àwọn opó Àlùfáà.

23 Wọn ní láti fi ìyàtọ̀ tí ó wà nínú mímọ́ àti aláìmọ́ kọ́ àwọn ènìyàn mi, kí wọn sì fi bi wọn yóò ṣe dá aláìmọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí mímọ́ hàn wọ́n.