30 Mósè àti àwọn àgbààgbà yìí sì padà sínú àgọ́.
31 Afẹ́fẹ́ sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì kó àparò wá láti inú òkun. Ó sì dà wọ́n káàkiri gbogbo ibùdó ní ìwọ̀n gíga ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta sórí ilẹ̀, bí ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan ní gbogbo àyíká.
32 Ní gbogbo ọjọ́ náà àti òru, títí dé ọjọ́ kejì ni àwọn ènìyàn fi ń kó àparò yìí: Ẹni tó kó kéré jù lọ kó ìwọ̀n hómérì mẹ́wáà, wọ́n sì sà wọ́n sílẹ̀ fún ara wọn yí gbogbo ibùdó.
33 Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹran náà sì wà láàrin eyín wọn, kó tó di pé wọ́n jẹ ẹ́, ìbínú Olúwa sì ru sí àwọn ènìyàn, ó sì pa wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn.
34 Torí èyí ni wọ́n ṣe pe ibẹ̀ ní Kíbírótì Hátafà nítorí pé níbẹ̀ ni wọ́n gbé sìnkú àwọn ènìyàn tó ní ọ̀kánjúà oúnjẹ sí.
35 Àwọn ènìyàn yóòkù sì gbéra láti Kíbírótì Hátafà lọ pa ibùdó sí Hásérótì wọ́n sì dúró nibẹ̀.