42 Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn péjọ lòdì sí Mósè àti Árónì, níwájú àgọ́ ìpàdé, lójijì ni ìkúùkù bolẹ̀, ògo Olúwa sì fara hàn.
43 Nígbà náà ni Mósè àti Árónì lọ ṣíwájú àgọ́ ìpàdé,
44 Olúwa sì sọ fún Mósè pé,
45 “Yàgò kúrò láàrin ìjọ ènìyàn yìí, kí ń ba le run wọ́n ní ìṣẹ́jú kan.” Wọ́n sì dojú bolẹ̀.
46 Mósè sì sọ fún Árónì pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárin ìjọ ènìyàn láti ṣètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú Olúwa ti jáde, àjàkálẹ̀-àrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.”
47 Árónì ṣe bí Mósè ti wí, ó sáré lọ sí àárin àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-àrùn ti bẹ̀rẹ̀ láàrin wọn, ṣùgbọ́n Árónì fín tùràrí, ó sì ṣe ètùtù fún wọn.
48 Ó dúró láàrin àwọn alààyè àti òkú, àjàkálẹ̀-àrùn náà sì dúró.