Nọ́ḿbà 20:11-17 BMY

11 Nígbà náà ni Mósè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu.

12 Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.”

13 Èyí ni omi ti Méríbà, níbi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti bá Olúwa jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrin wọn.

14 Mósè sì ránṣẹ́ láti Kádésì sí ọba Édómù, wí pé:“Èyí ni nǹkan tí arákùnrin rẹ Ísírẹ́lì sọ: Ìwọ ti mọ̀ nípa gbogbo ìnira, tí ó wá sí orí wa.

15 Àwọn bàbá ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Éjíbítì, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ará Éjíbítì ni wá lára àti àwọn bàbá wa,

16 ṣùgbọ́n nígbà tí a sunkún sí Olúwa, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán ańgẹ́lì kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Éjíbítì.“Báyìí àwa wà ní Kádésì, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ.

17 Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀ èdè rẹ kọjá, Àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kàǹga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.”