1 Ọkùnrin kan sì wà ni Kesaríà ti a ń pè ní Kọ̀nélíù, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Ítálì.
2 Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilé tilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo.
3 Níwọ̀n wákàtí kẹ́sàn-án ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere ańgẹ́lì Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Kọ̀nélíù!”
4 Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kí ni, Olúwa?”Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ ṣíwájú Ọlọ́run fún ìrántí.
5 Sì rán ènìyàn nísinsìnyìí lọ sí Jópà, kí wọn sì pe Símónì wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Pétérù.
6 Ó wọ̀ sí ilé Símónì aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”
7 Nígbà tí ańgẹ́lì náà tí ó bá Kọ̀nélíù sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, ati ọmọ ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo.