18 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́, wọ́n sì yin Ọlọ́run ógo wí pé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run fi ìrònúpíwàdà sí ìyè fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú!”
19 Nítorí náà àwọn tí a sì túká kiri ní ti inúnibíni tí ó dìde ní ti Sítéfánù, wọ́n rìn títí de Fonísíà, àti Kípíru, àti Ańtíókù, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnìkan bí kò ṣe fún kìkì àwọn Júù.
20 Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Sáípúrọ́sì àti Kírénè; nígbà tí wọ́n dé Áńtíókù, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Hélénì pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù Jésù Olúwa.
21 Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn: ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa.
22 Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerúsálémù; wọ́n sì rán Bánábà lọ títí dé Áńtíókù;
23 Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa.
24 Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa.