24 Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa.
25 Bánábà sì jáde lọ sí Tásọ́sì láti wá Ṣọ́ọ̀lù,
26 nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Áńtíókù. Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọ pọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀. Ní Áńtíókù ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni “Kírísítìánì.”
27 Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn wòlíì sì ti Jerúsálémù sọ̀kalẹ̀ wá sí Áńtíókù.
28 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Ágábù sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Róòmù. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìsèjọba Kíláúdíù.)
29 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arakùnrin tí ó wà ní Jùdíà.
30 Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi i ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù.