16 Pọ́ọ̀lù sì dìde dúró, ó sì juwọ́ sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin Ísírẹ́lì, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fi etí sílẹ̀ sí mi!
17 Ọlọ́run àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì yìí yan àwọn baba wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà lékè, nígbà tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì, apá gíga ni ó sì fi mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀,
18 ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrú fún ìwà wọn ní ijù,
19 nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kénááni, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní.
20 Gbogbo èyí sì sẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àádọ́ta-lé-ní-irínwó (450) ọdún. Lẹ̀yìn nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi onídájọ̀ fún wọn, títí ó fi di ìgbà Samueli wòlíì.
21 Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì bèèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, ọkùnrin kan nínú ẹ̀ya Bẹ́ńjámínì, fún ogójì ọdún.
22 Nígbà ti ó sì mú Ṣọ́ọ̀lù kúrò, ó gbé Dáfídì dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dáfídì ọmọ Jésè ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’