12 Wọn sì pe Bánábà ni Ṣeusi àti Pọ́ọ̀lù ni Hamisi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ síṣọ.
13 Àlùfáà Júpítérì, ẹni ti ilé òrìsà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn, ó sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu-ibode láti rúbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn àpósítélì wọ̀nyí.
14 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn àpósítélì Bánábà àti Pọ́ọ̀lù gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé:
15 “Ará, è é ṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìyìn rere fún yín, kí ẹ̀yin baà lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, àti òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.
16 Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà ti wọn.
17 Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.”
18 Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rúbọ bọ wọ́n.