22 wọn sì ń mú àwọn ẹ̀yìn lọ́kàn le, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú láti dúró ní ìgbàgbọ́, àti pé nínú ìpọ̀njú púpọ̀, ni àwa ó fi wọ ìjọba Ọlọ́run.
23 Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi à wọ́n lé ẹni gbàgbọ́ Olúwa lọ́wọ́.
24 Nígbà tí wọn sí la Pásídíà já, wọ́n wá sí Páḿfílíà.
25 Nígbà tí wọn sì ti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Págà, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ataláyà:
26 Àti láti ibẹ̀ lọ wọ́n ṣíkọ̀ lọ sí Ańtíókù ní ibi tí a gbé ti fi wọ́n lé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe parí
27 Nígbà tí wọ́n sì dé, tí wọ́n sì pé ìjọ jọ, wọ́n ròhìn gbogbo ohun tí Ọlọ́run fi wọ́n ṣe, àti bí ó ti ṣí ilẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn aláìkọlà.
28 Níbẹ̀ ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni ọjọ́ púpọ̀.