27 Nígbà tí onítúbú si tají, tí o sì ri pé, àwọn ìlẹ̀kùn túbú tí sí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣebí àwọn ara túbú ti sá lọ.
28 Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù gbé ohun rẹ̀ sókè, wí pé, “Má se pa ara rẹ lára: nítorí gbogbo wa ń bẹ níhìn yìí!”
29 Nígbà tí ó sì beere iná, ó bẹ́ wọ inú ilé, ó ń wárìrì, ó wólẹ̀ níwájú Pọ́ọ̀lù àti Sílà.
30 Ó sì mú wọn jáde, ó ní, “Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là?”
31 Wọ́n sì wí fún un pé, “Gbá Jéṣù Kírísítì Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là, ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ pẹ̀lú.”
32 Wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un, àti fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀.
33 Ó sì mú wọn ní wákàtí náà lóru, ó wẹ ọgbẹ́ wọn; a ṣi bamitíìsì rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójúkan náà.