29 Nígbà tí ó sì beere iná, ó bẹ́ wọ inú ilé, ó ń wárìrì, ó wólẹ̀ níwájú Pọ́ọ̀lù àti Sílà.
30 Ó sì mú wọn jáde, ó ní, “Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là?”
31 Wọ́n sì wí fún un pé, “Gbá Jéṣù Kírísítì Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là, ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ pẹ̀lú.”
32 Wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un, àti fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀.
33 Ó sì mú wọn ní wákàtí náà lóru, ó wẹ ọgbẹ́ wọn; a ṣi bamitíìsì rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójúkan náà.
34 Ó sì mú wọn wá ṣí ilé rẹ̀, ó sì gbé ounjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́.
35 Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn onídájọ́ rán àwọn ọlọ́pàá pé, “Tú àwọn ènìyàn náà ṣílẹ̀.”