6 Wọ́n sì la agbégbé Fírígíà já, àti Gálátíà, nítorí tí Ẹ̀mí Mímọ́ kọ̀ fún wọn láti ṣọ ọ̀rọ̀ náà ni Éṣíà.
7 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀kánkán Mísíà, wọ́n gbìyànjú láti lọ ṣí Bítíníà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Jéṣù kò gbà fún wọn.
8 Nígbà tí wọ́n sì kọjà lẹ́bá Mísíà, wọ́n ṣọ̀kalẹ̀ lọ ṣi Tíróásì.
9 Ìran kan si hàn sì Pọ́ọ̀lù ni òru: Ọkùnrin kan ará Makedóníà dúró, ó sì ńbẹ̀ ẹ̀, wí pé, “Rékọjá wá ṣí Makedóníà, kí o sí ràn wá lọ́wọ́!”
10 Nígbà tí ó sì tí rí ìran náà, lọ́gán ó múra láti lọ sí Makedóníà, a gbà á sí pé, Olúwa tí pè wá láti wàásù ìyìn rere fún wọn.
11 Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Tíróáṣì a ba ọ̀nà tàrà lọ ṣí Sámótírakíà, ni ijọ́ kéjì a sì dé Níápólì;
12 Láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Fílípì, Ìlú kan tí (àwọn ara Róòmù) tẹ̀dó tí í ṣe olú ìlú yìí fún ọjọ́ mélòókán.