8 Nígbà tí wọ́n sì kọjà lẹ́bá Mísíà, wọ́n ṣọ̀kalẹ̀ lọ ṣi Tíróásì.
9 Ìran kan si hàn sì Pọ́ọ̀lù ni òru: Ọkùnrin kan ará Makedóníà dúró, ó sì ńbẹ̀ ẹ̀, wí pé, “Rékọjá wá ṣí Makedóníà, kí o sí ràn wá lọ́wọ́!”
10 Nígbà tí ó sì tí rí ìran náà, lọ́gán ó múra láti lọ sí Makedóníà, a gbà á sí pé, Olúwa tí pè wá láti wàásù ìyìn rere fún wọn.
11 Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Tíróáṣì a ba ọ̀nà tàrà lọ ṣí Sámótírakíà, ni ijọ́ kéjì a sì dé Níápólì;
12 Láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Fílípì, Ìlú kan tí (àwọn ara Róòmù) tẹ̀dó tí í ṣe olú ìlú yìí fún ọjọ́ mélòókán.
13 Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà; àwa sí jókóò, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ ṣọ̀rọ̀.
14 Àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Lìdíà, tí ó ń ta àwọn aró ẹlẹ́ṣè àlùkò, gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ọkàn ẹni tí Olúwa ṣí láti fetísì ohun tí a tí ẹnu Pọ́ọ̀lù sọ.