3 Ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ irú bamítíìsímù wo ni a bamitíìsímù yín sí?”Wọ́n sì wí pé, “Sí bamitíìsímù tí Jòhánù.”
4 Pọ́ọ̀lù sí wí pé, “Nítọ̀ọ́tọ́, ní Jòhánù fi bamitíìsímù tí ìrònúpìwàdà bamitíìsímù, ó ń wí fún àwọn ènìyàn pé, kí wọ́n gba ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́, èyí sì ni Kírísítì Jésù.”
5 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, a bamitíìsímù wọn lórúkọ Jéṣù Olúwa.
6 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn: wọ́n sì ń fọ́ èdè mìíràn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.
7 Iye àwọn ọkùnrin náà gbogbo tó méjìlá.
8 Nígbà tí ó sì wọ inú Sínágọ́gù lọ ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni oṣù mẹ́ta, ó ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó sì ń yí wọn lọ́kàn padà sí nǹkan tí i ṣe tí ìjọba Ọlọ́run.
9 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoójúmọ́ ni ilé-ìwé Tíráńnù.