1 Lẹ́yìn tí àwa ti kúrò lọ́dọ̀ wọn, tí a sì ṣíkọ̀, àwa bá ọ̀nà wa lọ tàrà sí Kúúsì. Ní ijọ́ kéjì a sì lọ sí Ródésì, àti gba ibẹ̀ lọ sí Pátarà:
2 A rí ọkọ̀ ojú-omi kan tí ń rékọ́ja lọ sí Fonísíà, a wọ inú ọkọ̀ náà, a sì síkọ̀.
3 Nígbà tí àwa sì ń wo Sáípúrọ́sì lókèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Síríà, a sì gúnlẹ̀ ni Tírè; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù ṣílẹ̀.
4 Nígbà tí a sì ti rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níbẹ̀, a dúró ní ọ̀dọ̀ wọn níbẹ̀ fún ijọ́ méje: àwọn ẹni tí ó ti ipá Ẹ̀mí wí fún Pọ́ọ̀lù pé, kí ó má ṣe lọ sí Jerúsálémù.