12 “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Ananáyà tọ̀ mí wá, ẹni tó jẹ́ olùfọkànṣìn ti òfin, tí ó sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn Júù tí ó ń gbé ibẹ̀.
13 Ó sì dúró tì mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Arákùnrin Ṣọ́ọ̀lù, gba ìríran!’ Ní ẹsẹ̀ kan náà, mo sì sí ojú sí òkè mo sì lè rí i.
14 “Nígbà náà ni ó wí pé: ‘Ọlọ́run àwọn baba wa ti yàn ọ́ láti mọ ìfẹ́ rẹ̀, àti láti ri Ẹni Òdodo náà, àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu rẹ̀.
15 Ìwọ yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn, nínú ohun tí ìwọ tí rí tí ìwọ sì ti gbọ́.
16 Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, kín ni ìwọ ń dúró dè? Dìde, kí a sì bamitíìsì rẹ̀, kí ó sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù, kí ó sì máa pé orúkọ rẹ̀.’
17 “Nígbà tí mo padà wá sí Jerúsálémù tí mo ǹ gbàdúrà ní tẹ́ḿpílì, mo bọ́ sí ojúran,
18 mo sì rí Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ fún mi pé, ‘Kíá! Jáde kúrò ní Jerúsálémù kán-kán, nítorí wọn kì yóò gba ẹ̀rí rẹ nípa mi gbọ́.’