26 Nígbà tí balógun ọ̀rún sì gbọ́ èyí, ó lọ wí fún olórí-ogun pé, “Kín ni ó fẹ́ ṣe yìí: nítorí ọkùnrin yìí ará Róòmù ní i ṣe?”
27 Olórí-ogun sì dé, ó sì bí Pọ́ọ̀lù pé, “Sọ fún mi, ará Róòmù ni ìwọ jẹ́ bí?”Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”
28 Olórí-Ogun sì dáhùn wí pé, “Owó púpọ̀ ni mo fi ra ọlá ìbílẹ̀ yìí.”Pọ́ọ̀lù wí pé, “Ṣùgbọn a bí mi sínú rẹ̀ ni.”
29 Nítorí náà àwọn tí ó múra láti fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: lójúkan náà. Ọlórí-ogun pẹ̀lú sì bẹ̀rù nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ní Pọ́ọ̀lù i ṣe, àti nítorí ó tí dè é.
30 Ní ijọ́ kéjì, nítorí tí olórí-ogun fẹ́ mọ̀ dájúdájú ohun tí àwọn Júù ń fi Pọ́ọ̀lù sùn sí, ó túu sílẹ̀, ó pàṣẹ kí àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ péjọ, nígbà náà ni ó mú Pọ́ọ̀lù sọ̀kalẹ̀, ó sì mú un dúró ní wájú wọn.